NỌMBA 14:17-18

NỌMBA 14:17-18 YCE

Nítorí náà OLUWA, èmi bẹ̀ Ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ pé, ‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’