Mat 27:62-66
Mat 27:62-66 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu, Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde. Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mã lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e. Bẹ̃ni nwọn lọ, nwọn si se iboji na daju, nwọn fi edídí dí okuta na, nwọn si yàn iṣọ.
Mat 27:62-66 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji, ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ̀dún, àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ Pilatu. Wọ́n ní, “Alàgbà, a ranti pé ẹlẹ́tàn nì sọ nígbà tí ó wà láàyè pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹta òun óo jí dìde. Nítorí náà, pàṣẹ kí wọ́n ṣọ́ ibojì náà títí di ọjọ́ kẹta. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lè wá jí òkú rẹ̀ lọ, wọn yóo wá wí fún àwọn eniyan pé, ‘Ó ti jinde kúrò ninu òkú.’ Ìtànjẹ ẹẹkeji yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” Pilatu bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ ní olùṣọ́. Ẹ lọ fi wọ́n ṣọ́ ibojì náà bí ó ti tọ́ lójú yín.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sé ẹnu ibojì náà, wọ́n fi èdìdì sí ara òkúta tí wọ́n gbé dí i. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sibẹ pẹlu.
Mat 27:62-66 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.” Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.