Mat 24:36-40,44 - Compare All Versions
Mat 24:36-40 YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio si ri. Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, Nwọn kò si mọ̀ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ.
Mat 24:44 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de.
Mat 24:36-40 YCE (Yoruba Bible)
“Kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ náà ati wakati náà. Àwọn angẹli ọ̀run kò mọ̀ ọ́n; ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan ni ó mọ̀ ọ́n. Nítorí bí ó ti rí ní ìgbà Noa, bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Nítorí ní àkókò náà, kí ìkún-omi tó dé, ńṣe ni wọ́n ń jẹ, tí wọn ń mu, wọ́n ń gbé iyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí ó fi di ọjọ́ tí Noa wọ inú ọkọ̀. Wọn kò fura títí ìkún-omi fi dé, tí ó gba gbogbo wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Àwọn meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.
MATIU 24:44 YCE (Yoruba Bible)
Nítorí náà, kí ẹ̀yin náà wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wakati tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.
Mat 24:36-40 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Noa fi bọ́ sínú ọkọ̀. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn. Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a o mú ẹnìkan, a ó sì fi ẹni kejì sílẹ̀.
Matiu 24:44 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.