MATIU 24:36-40, 44

MATIU 24:36-40 YCE

“Kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ náà ati wakati náà. Àwọn angẹli ọ̀run kò mọ̀ ọ́n; ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan ni ó mọ̀ ọ́n. Nítorí bí ó ti rí ní ìgbà Noa, bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Nítorí ní àkókò náà, kí ìkún-omi tó dé, ńṣe ni wọ́n ń jẹ, tí wọn ń mu, wọ́n ń gbé iyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí ó fi di ọjọ́ tí Noa wọ inú ọkọ̀. Wọn kò fura títí ìkún-omi fi dé, tí ó gba gbogbo wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí. Àwọn meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.

MATIU 24:44 YCE

Nítorí náà, kí ẹ̀yin náà wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wakati tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.

Àwọn fídíò fún MATIU 24:36-40,44