Ẹk. Jer 3:1-6
Ẹk. Jer 3:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.
Ẹk. Jer 3:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú, tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí, ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun, ó sì ti fọ́ egungun mi. Ó dótì mí, ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri. Ó fi mí sinu òkùnkùn bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.
Ẹk. Jer 3:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ. Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀; Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́. Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi. Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.