ẸKÚN JEREMAYA 3:1-6

ẸKÚN JEREMAYA 3:1-6 YCE

Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú, tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí, ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun, ó sì ti fọ́ egungun mi. Ó dótì mí, ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri. Ó fi mí sinu òkùnkùn bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.