Joṣ 19:32-48

Joṣ 19:32-48 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ipín kẹfa yọ fun awọn ọmọ Naftali, ani fun awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn. Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Helefu, lati igi-oaku Saanannimu, ati Adami-nekebu, ati Jabneeli dé Lakkumu; o si yọ si Jordani. Àla na si ṣẹri lọ sí ìha ìwọ-õrùn si Asnoti-taboru, o si ti ibẹ̀ lọ si Hukkoki; o si dé Sebuluni ni gusù, o si dé Aṣeri ni ìwọ-õrùn, ati Juda ni Jordani ni ìha ìla-õrùn. Awọn ilu olodi si ni Siddimu, Seri, ati Hammati, Rakkati, ati Kinnereti; Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru; Ati Kedeṣi, ati Edrei, ati Eni-hasoru; Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn. Ilẹ keje yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn. Àla ilẹ-iní wọn si ni Sora, ati Eṣtaolu, ati Iri-ṣemeṣi; Ati Ṣaalabbini, ati Aijaloni, ati Itla; Ati Eloni, ati Timna, ati Ekroni; Ati Elteke, ati Gibbetoni, ati Baalati; Ati Jehudi, ati Bene-beraki, ati Gati-rimmọni; Ati Me-jarkoni, ati Rakkoni, pẹlu àla ti mbẹ kọjusi Jọppa. Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Joṣ 19:32-48 Yoruba Bible (YCE)

Ilẹ̀ kẹfa tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Nafutali, Ààlà ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní Helefi, láti ibi igi oaku tí ó wà ní Saananimu, Adaminekebu, ati Jabineeli, títí dé Lakumu, ó sì pin sí odò Jọdani. Níbẹ̀ ni ààlà náà ti yipada lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn sí Asinotu Tabori. Láti ibẹ̀, ó lọ títí dé Hukoku, ó lọ kan ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni ní apá ìhà gúsù, ó sì kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri lápá ìwọ̀ oòrùn, ati ti Juda ní apá ìlà oòrùn létí odò Jọdani. Àwọn ìlú olódi tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni Sidimu, Seri, Hamati, Rakati, Kinereti; Adama, Rama, Hasori; Kedeṣi, Edirei, Enhasoru, Yironi, Migidalieli, Horemu, Betanati ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo ìlú ati àwọn ìletò wọn jẹ́ mọkandinlogun. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Nafutali gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ keje tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Dani. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Sora, Ẹṣitaolu, Iriṣemeṣi; Ṣaalibimu, Aijaloni, Itila, Eloni, Timna, Ekironi, Eliteke, Gibetoni, Baalati; Jehudi, Beneberaki, Gati Rimoni ati Mejakoni, ati Rakoni pẹlu agbègbè tí ó dojú kọ Jọpa. Nígbà tí ilẹ̀ ẹ̀yà Dani bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n bá lọ gbógun ti ìlú Leṣemu, wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Wọ́n yí orúkọ Leṣemu pada sí Dani, tíí ṣe orúkọ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọnyi ni ìpín tí ó kan ẹ̀yà Dani gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Joṣ 19:32-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìpín kẹfà jáde fún Naftali, agbo ilé ní agbo ilé: Ààlà wọn lọ láti Helefi àti igi ńlá ní Saananimu nímù; kọjá lọ sí Adami Nekebu àti Jabneeli dé Lakkumu, ó sì pín ní Jordani. Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Asnoti-Tabori ó sì jáde ní Hukoki. Ó sì dé Sebuluni, ní ìhà gúúsù Aṣeri ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Juda ní Jordani ní ìhà ìlà-oòrùn. Àwọn ìlú olódi sì Siddimu, Seri, Hamati, Rakàti, Kinnereti, Adama, Rama Hasori, Kedeṣi, Edrei, Eni-Aṣọri, Ironi, Migdali-Eli, Horemu, Beti-Anati àti Beti-Ṣemeṣi. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàn-dínlógún àti ìletò wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Naftali, ní agbo ilé sí agbo ilé. Ìbò kéje jáde fún ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé ní agbo ilé. Ilẹ̀ ìní wọn nìwọ̀nyí: Sora, Eṣtaoli, Iri-Ṣemesi, Ṣaalabini, Aijaloni, Itila, Eloni, Timna, Ekroni, Elteke, Gibetoni, Baalati, Jehudu, Bene-Beraki, Gati-Rimoni, Me Jakoni àti Rakkoni, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Joppa. (Ṣùgbọ́n àwọn ará Dani ní ìṣòro láti gba ilẹ̀ ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Leṣemu, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Leṣemu, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dani orúkọ baba ńlá wọn). Àwọn ìlú wọ́n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé agbo ilé.