Ìpín kẹfà jáde fún Naftali, agbo ilé ní agbo ilé:
Ààlà wọn lọ láti Helefi àti igi ńlá ní Saananimu nímù; kọjá lọ sí Adami Nekebu àti Jabneeli dé Lakkumu, ó sì pín ní Jordani. Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Asnoti-Tabori ó sì jáde ní Hukoki. Ó sì dé Sebuluni, ní ìhà gúúsù Aṣeri ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Juda ní Jordani ní ìhà ìlà-oòrùn.
Àwọn ìlú olódi sì Siddimu, Seri, Hamati, Rakàti, Kinnereti, Adama, Rama Hasori, Kedeṣi, Edrei, Eni-Aṣọri, Ironi, Migdali-Eli, Horemu, Beti-Anati àti Beti-Ṣemeṣi.
Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàn-dínlógún àti ìletò wọn.
Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Naftali, ní agbo ilé sí agbo ilé.
Ìbò kéje jáde fún ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé ní agbo ilé. Ilẹ̀ ìní wọn nìwọ̀nyí:
Sora, Eṣtaoli, Iri-Ṣemesi, Ṣaalabini, Aijaloni, Itila, Eloni, Timna, Ekroni, Elteke, Gibetoni, Baalati, Jehudu, Bene-Beraki, Gati-Rimoni, Me Jakoni àti Rakkoni, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Joppa.
(Ṣùgbọ́n àwọn ará Dani ní ìṣòro láti gba ilẹ̀ ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Leṣemu, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Leṣemu, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dani orúkọ baba ńlá wọn).
Àwọn ìlú wọ́n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé agbo ilé.