Joṣ 19:17-31
Joṣ 19:17-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ipín kẹrin yọ fun Issakari, ani fun awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn. Àla wọn si dé Jesreeli, ati Kesuloti, ati Ṣunemu; Ati Hafaraimu, ati Ṣihoni, ati Anaharati; Ati Rabbiti, Kiṣioni, ati Ebesi; Ati Remeti, ati Eni-gannimu, ati Enhadda, ati Beti-passesi; Àla na si dé Tabori, ati Ṣahasuma, ati Beti-ṣemeṣi; àla wọn yọ si Jordani: ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi ati ileto wọn. Ipín karun yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn. Àla wọn si ni Helkati, ati Hali, ati Beteni, ati Akṣafu; Ati Allammeleki, ati Amadi, ati Miṣali; o si dé Karmeli ni ìha ìwọ-õrùn, ati Ṣihorilibnati; O si ṣẹri lọ si ìha ìla-õrùn dé Beti-dagoni, o si dé Sebuluni, ati afonifoji Ifta-eli ni ìha ariwa dé Betemeki, ati Neieli; o si yọ si Kabulu li apa òsi, Ati Ebroni, ati Rehobu, ati Hammoni, ati Kana, ani titi dé Sidoni nla; Àla na si ṣẹri lọ si Rama, ati si Tire ilu olodi; àla na si ṣẹri lọ si Hosa; o si yọ si okun ni ìha Aksibu: Ati Umma, ati Afeki, ati Rehobu: ilu mejilelogun pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
Joṣ 19:17-31 Yoruba Bible (YCE)
Ilẹ̀ kẹrin tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Isakari. Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu; Hafaraimu, Sihoni, Anaharati; Rabiti, Kiṣioni, Ebesi; Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi. Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun. Àwọn ni ìlú ati ìletò náà tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Isakari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ karun-un tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Aṣeri. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Helikati, Hali, Beteni, Akiṣafu. Alameleki, Amadi, ati Miṣali, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ náà dé Kamẹli ati Ṣihori Libinati. Ààlà rẹ̀ wá yípo lọ sí apá ìlà oòrùn, títí dé Beti Dagoni, títí dé Sebuluni ati àfonífojì Ifitaeli ní apá àríwá Betemeki ati Neieli. Lẹ́yìn náà ó tún lọ ní apá ìhà àríwá náà títí dé Kabulu, Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá; Lẹ́yìn náà, ààlà náà yípo lọ sí Rama; ó dé ìlú olódi ti Tire, lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí Hosa, ó sì pin sí etíkun. Ninu ilẹ̀ wọn ni Mahalabu, Akisibu; Uma, Afeki, ati Rehobu wà, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejilelogun. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Aṣeri gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Joṣ 19:17-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kèké kẹrin jáde fún Isakari, agbo ilé ní agbo ilé. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Jesreeli, Kesuloti, Ṣunemu, Hafraimu, Ṣihoni, Anaharati, Rabiti, Kiṣioni, Ebesi, Remeti, Eni-Gannimu, Eni-Hada àti Beti-Pasesi. Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìn-dínlógún àti ìletò wọn. Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Isakari, ní agbo ilé agbo ilé. Kèké karùn-ún jáde fún ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Helikati, Hali, Beteni, Akṣafu, Allameleki, Amadi, àti Miṣali. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Karmeli àti Ṣihori-Libinati. Nígbà náà ni o yí sí ìhà ìlà-oòrùn Beti-Dagoni, dé Sebuluni àti Àfonífojì Ifita-Eli, ó sì lọ sí àríwá sí Beti-Emeki àti Neieli, ó sì kọjá lọ sí Kabuli ní apá òsì. Ó sì lọ sí Abdoni, Rehobu, Hammoni àti Kana títí dé Sidoni ńlá. Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rama, ó sì lọ sí ìlú olódi Tire, ó sì yà sí Hosa, ó sì jáde ní Òkun ní ilẹ̀ Aksibu, Uma, Afeki àti Rehobu. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.