Joṣua 19:17-31

Joṣua 19:17-31 YCB

Kèké kẹrin jáde fún Isakari, agbo ilé ní agbo ilé. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Jesreeli, Kesuloti, Ṣunemu, Hafraimu, Ṣihoni, Anaharati, Rabiti, Kiṣioni, Ebesi, Remeti, Eni-Gannimu, Eni-Hada àti Beti-Pasesi. Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìn-dínlógún àti ìletò wọn. Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Isakari, ní agbo ilé agbo ilé. Kèké karùn-ún jáde fún ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Helikati, Hali, Beteni, Akṣafu, Allameleki, Amadi, àti Miṣali. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Karmeli àti Ṣihori-Libinati. Nígbà náà ni o yí sí ìhà ìlà-oòrùn Beti-Dagoni, dé Sebuluni àti Àfonífojì Ifita-Eli, ó sì lọ sí àríwá sí Beti-Emeki àti Neieli, ó sì kọjá lọ sí Kabuli ní apá òsì. Ó sì lọ sí Abdoni, Rehobu, Hammoni àti Kana títí dé Sidoni ńlá. Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rama, ó sì lọ sí ìlú olódi Tire, ó sì yà sí Hosa, ó sì jáde ní Òkun ní ilẹ̀ Aksibu, Uma, Afeki àti Rehobu. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.