Job 9:1-13
Job 9:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOBU si dahùn o si wipe, Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun? Bi o ba ṣepe yio ba a jà, on kì yio lè idá a lohùn kan ninu ẹgbẹrun ọ̀ran. Ọlọgbọ́n-ninu ati alagbara ni ipá li on; tali o ṣagidi si i, ti o si gbè fun u ri? Ẹniti o ṣi okè ni idi, ti nwọn kò si mọ̀: ti o tari wọn ṣubu ni ibinu rẹ̀. Ti o mì ilẹ aiye tìti kuro ni ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ si mì tìti. Ti o paṣẹ fun õrùn, ti on kò si là, ti o si dí irawọ̀ mọ́. On nikanṣoṣo li o na oju ọrun lọ, ti o si nrìn lori ìgbì okun. Ẹniti o da irawọ̀ Arketuru, Orioni ati Pleiade ati iyàra pipọ ti gusu. Ẹniti nṣe ohun ti o tobi jù awari lọ, ani ohun iyanu laini iye. Kiyesi i, on kọja lọ li ẹ̀ba ọdọ mi, emi kò si ri i, o si kọja siwaju, bẹ̃li emi kò ri oju rẹ̀. Kiyesi i, o jãgbà lọ, tani yio fa a pada? tani yio bi i pe, kini iwọ nṣe nì? Ọlọrun kò ni fà ibinu rẹ̀ sẹhin, awọn oniranlọwọ ìgberaga a si tẹriba labẹ rẹ̀.
Job 9:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Jobu dáhùn pé: “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn, olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè. Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀, agbára rẹ̀ sì pọ̀. Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ? Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀; tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú. Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì. Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé; òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀. Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run: Beari, Orioni, ati Pileiadesi ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù. Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà. Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i, ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀. Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà, ta ló lè dá a dúró? Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’ “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.
Job 9:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jobu sì dáhùn ó sì wí pé: “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́. Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run? Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà, òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀. Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun; ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí? Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀. Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀, ọwọ́n rẹ̀ sì mì tìtì. Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn, kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́. Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run, ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun. Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari, Orioni àti Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù. Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ, àní ohun ìyanu láìní iye. Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀. Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà? Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì? Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn, àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.