JOBU 9:1-13

JOBU 9:1-13 YCE

Jobu dáhùn pé: “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn, olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè. Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀, agbára rẹ̀ sì pọ̀. Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ? Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀; tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú. Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì. Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé; òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀. Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run: Beari, Orioni, ati Pileiadesi ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù. Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà. Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i, ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀. Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà, ta ló lè dá a dúró? Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’ “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.