Job 7:11-21
Job 7:11-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina emi kì yio pa ẹnu mi mọ, emi o ma sọ ninu irora ọkàn mi, emi o ma ṣe irahùn ninu kikoro ọkàn mi. Emi ama iṣe ejo okun tabi erinmi, ti iwọ fi yàn oluṣọ tì mi? Nigbati mo wipe, ibusùn mi yio tù mi lara, itẹ mi yio gbé ẹrù irahùn mi pẹlu. Nigbana ni iwọ fi alá da mi niji, iwọ si fi iran oru dẹrubà mi. Bẹ̃li ọkàn mi yan isà okú jù aye, ikú jù egungun mi lọ. O su mi, emi kò le wà titi: jọwọ mi jẹ, nitoripe asan li ọjọ mi. Kili enia ti iwọ o ma kokìki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e? Ati ti iwọ o fi ma wa ibẹ̀ ẹ wò li orowurọ̀, ti iwọ o si ma dán a wò nigbakũgba! Yio ti pẹ́ to ki iwọ ki o to fi mi silẹ̀ lọ, ti iwọ o fi jọ mi jẹ titi emi o fi le dá itọ mi mì. Emi ti ṣẹ̀, kili emi o ṣe si ọ, iwọ Olùtọju enia? ẽṣe ti iwọ fi fi mi ṣe àmi itasi niwaju rẹ, bẹ̃li emi si di ẹrù-wuwo si ara rẹ? Ẽṣe ti iwọ kò si dari irekọja mi jì, ki iwọ ki o si mu aiṣedede mi kuro? njẹ nisisiyi li emi iba sùn ninu erupẹ, iwọ iba si wá mi kiri li owurọ̀, emi ki ba ti si.
Job 7:11-21 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, n kò ní dákẹ́; n óo sọ ìrora ọkàn mi; n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde. Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi, tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí? Nígbà tí mo wí pé, ‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára, ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’. Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí, tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà, kí n lè fara mọ́ ọn pé ó sàn kí á lọ́ mi lọ́rùn pa, kí n sì lè yan ikú dípò pé kí n wà láàyè. Ayé sú mi, n kò ní wà láàyè títí lae. Ẹ fi mí sílẹ̀, nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga, tí o sì fi ń náání rẹ̀; tí ò ń bẹ̀ ẹ́ wò láràárọ̀, tí o sì ń dán an wò nígbà gbogbo? Yóo ti pẹ́ tó kí ẹ tó mójú kúrò lára mi? Kí ẹ tó fi mí lọ́rùn sílẹ̀ kí n rí ààyè dá itọ́ mì? Bí mo bá ṣẹ̀, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ́ mi? Kí ló dé tí ẹ fi dójú lé mi, tí mo di ẹrù lọ́rùn yín? Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí kí ẹ sì fojú fo àìdára mi? Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn n kò ní sí mọ́.”
Job 7:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́, èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi, èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi. Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú, tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi? Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú. Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi, ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ. O sú mi, èmi kò le wà títí: jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi. “Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀? Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e? Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀, ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkúgbà! Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ, tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì. Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ. Ìwọ Olùsójú ènìyàn? Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe ààmì itasi níwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ? Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn, kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò? Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀, ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”