Job 5:1-16

Job 5:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ pè nisisiyi! bi ẹnikan ba wà ti yio da ọ lohùn, tabi tani ninu awọn ẹni-mimọ́ ti iwọ o wò? Nitoripe ibinu pa alaimoye, irúnu a si pa òpe enia. Emi ti ri alaimoye ti o ta gbongbò mulẹ̀, ṣugbọn lojukanna mo fi ibujoko rẹ̀ bú. Awọn ọmọ rẹ̀ kò jina sinu ewu, a si tẹ̀ wọn mọlẹ loju ibode, bẹ̃ni kò si alãbò kan. Ikore oko ẹniti awọn ẹniti ebi npa jẹrun, ti nwọn si wọnú ẹ̀gun lọ ikó, awọn igara si gbe ohùn ini wọn mì. Bi ipọnju kò tilẹ̀ tinu erupẹ jade wá nì, ti iyọnu kò si tinu ilẹ hù jade wá. Ṣugbọn a bi enia sinu wàhala, gẹgẹ bi ìpẹpẹ iná ti ima ta sokè. Sọdọ Ọlọrun li emi lè ma ṣe awári, li ọwọ Ọlọrun li emi lè ma fi ọ̀ran mi le. Ẹniti o ṣe ohun ti o tobi, ti a kò lè iṣe awári, ohun iyanu laini iye. Ti nrọ̀jo si ilẹ aiye, ti o si nrán omi sinu ilẹ̀kilẹ. Lati gbe awọn onirẹlẹ leke, ki a le igbé awọn ẹni ibinujẹ ga si ibi ailewu. O yi ìmọ awọn alarekerekè po, bẹ̃li ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ. O mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke ara wọn, ati ìmọ awọn onroro li o tãri ṣubu li ògedengbè. Nwọn sure wọ inu òkunkun li ọ̀san, nwọn si nfọwọ talẹ̀ li ọ̀sangangan bi ẹnipe li oru. Ṣugbọn o gba talakà là kuro li ọwọ idà, lọwọ ẹnu wọn, ati lọwọ awọn alagbara. Bẹ̃ni abá wà fun talaka, aiṣotitọ si pa ẹnu rẹ̀ mọ.

Job 5:1-16 Yoruba Bible (YCE)

“Pe ẹnìkan nisinsinyii; ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn? Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ? Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀, owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan. Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀, ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú. Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè, kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là. Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gún ni ó ti mú un jáde, àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri. Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde. A bí eniyan sinu wahala bí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè. “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA, n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́; ẹni tíí ṣe ohun ńlá tí eniyan kò lè rídìí, ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà. A máa rọ òjò sórí ilẹ̀, a sì máa bomi rin oko. A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga, a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́. A máa da ète àwọn alárèékérekè rú, kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn; ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin. Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan, wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni. Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn, ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára. Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka, a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

Job 5:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn? Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí? Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn. Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú. Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan. Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì. Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni, tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá. Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà, gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè. “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀, ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé. Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí, ohun ìyanu láìní iye. Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀. Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu. Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé. Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán; wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni. Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà, àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.