JOBU 5:1-16

JOBU 5:1-16 YCE

“Pe ẹnìkan nisinsinyii; ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn? Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ? Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀, owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan. Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀, ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú. Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè, kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là. Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gún ni ó ti mú un jáde, àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri. Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde. A bí eniyan sinu wahala bí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè. “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA, n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́; ẹni tíí ṣe ohun ńlá tí eniyan kò lè rídìí, ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà. A máa rọ òjò sórí ilẹ̀, a sì máa bomi rin oko. A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga, a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́. A máa da ète àwọn alárèékérekè rú, kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn; ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin. Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan, wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni. Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn, ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára. Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka, a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.