Job 31:1-12
Job 31:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI ti bá oju mi da majẹmu, njẹ emi o ha ṣe tẹjumọ wundia? Nitoripe kini ipin Ọlọrun lati ọrun wá, tabi kini ogún Olodumare lati oke ọrun wá? Kò ṣepe awọn enia buburu ni iparun wà fun, ati ìṣẹniṣẹ fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ? On kò ha ri ipa-ọ̀na mi, on kò ha si ka gbogbo iṣiṣe mi? Bi o ba ṣepe emi ba fi aiṣotitọ rìn, tabi ti ẹsẹ mi si yara si ẹ̀tan. Ki a diwọn mi ninu iwọ̀n ododo, ki Ọlọrun le imọ̀ iduroṣinṣin mi. Bi ẹsẹ mi ba yà kuro loju ọ̀na, ti aiya mi si tẹ̀le ipa oju mi, bi àbawọn kan ba si lẹmọ́ mi li ọwọ. Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu. Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ iba deni ni ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi, Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀. Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ. Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu.
Job 31:1-12 Yoruba Bible (YCE)
“Mo ti bá ojú mi dá majẹmu; n óo ṣe wá máa wo wundia? Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè? Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare? Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo, àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀. Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi, ó sì mọ ìrìn mi. Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo, tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, (kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́, yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!) Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà, tí mò ń ṣe ojúkòkòrò, tí ọwọ́ mi kò sì mọ́, jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi, kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu. “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin, tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi; jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn, kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀. Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù, ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún. Iná ajónirun ni, tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀.
Job 31:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú, èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá? Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá? Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá. Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀? Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi? “Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn; (Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.) Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́, Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu. “Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi, Kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀. Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀ Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.