JOBU 31:1-12

JOBU 31:1-12 YCE

“Mo ti bá ojú mi dá majẹmu; n óo ṣe wá máa wo wundia? Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè? Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare? Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo, àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀. Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi, ó sì mọ ìrìn mi. Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo, tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, (kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́, yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!) Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà, tí mò ń ṣe ojúkòkòrò, tí ọwọ́ mi kò sì mọ́, jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi, kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu. “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin, tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi; jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn, kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀. Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù, ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún. Iná ajónirun ni, tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀.