Job 23:13-17
Job 23:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn oninukan li on, tani yio si yi i pada? Eyiti ọkàn rẹ̀ si ti fẹ, eyi na ni iṣe. Nitõtọ ohun ti ati yàn silẹ fun mi ni nṣe, ọ̀pọlọpọ iru bẹ li o wà li ọwọ rẹ̀. Nitorina ni ara ko ṣe rọ̀ mi niwaju rẹ̀, nigbati mo ba rò o, ẹ̀ru a ba mi. Nitoripe Ọlọrun ti pá mi li aiya, Olodumare si ndamu mi. Nitoriti a kò ti ke mi kuro niwaju òkunkun, bẹ̃ni kò pa òkùnkùn-biribiri mọ kuro niwaju mi.
Job 23:13-17 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada, kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada. Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe. Yóo ṣe ohun tí ó ti pinnu láti ṣe fún mi ní àṣeyọrí, ati ọpọlọpọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yòókù tí ó tún ní lọ́kàn láti ṣe fún mi. Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀, tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí. Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, Olodumare ti dẹ́rùbà mí. Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká, òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú.
Job 23:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe. Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀. Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi. Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olódùmarè sì ń dààmú mi. Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.