Job 21:1-16
Job 21:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
SUGBỌN Jobu dahùn, o si wipe, Ẹ tẹti silẹ dẹdẹ si ohùn mi, ki eyi ki o jasi itunu nyin. Ẹ jọwọ mi ki emi sọ̀rọ, lẹhin igbati mo ba sọ tan, iwọ ma fi ṣẹsin nṣo. Bi o ṣe ti emi ni, aroye mi iṣe si enia bi, tabi ẽtiṣe ti ọkàn mi kì yio fi ṣe aibalẹ? Ẹ wò mi fin, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki ẹ si fi ọwọ le ẹnu nyin. Ani nigbati mo ranti, ẹ̀ru bà mi, iwarìri si mu mi lara. Nitori kini enia buburu fi wà li ãyè, ti nwọn gbọ́, ani ti nwọn di alagbara ni ipa! Iru-ọmọ wọn fi idi kalẹ li oju wọn pẹlu wọn, ati ọmọ-ọmọ wọn li oju wọn. Ile wọn wà laini ewu, bẹ̃ni ọpa-ìna Ọlọrun kò si lara wọn. Akọ-malu wọn a ma gùn, kì isi isé, abomalu wọn a ma bi, ki isi iṣẹnu; Nwọn a ma rán awọn ọmọ wọn wẹwẹ jade bi agbo ẹran, awọn ọmọ wọn a si ma jó. Nwọn mu ohun ọnà orin timbreli ati dùru, nwọn si nyọ̀ si ohùn ifère. Nwọn lo ọjọ wọn ninu ọrọ̀; ni iṣẹjukan nwọn a lọ si ipo-okú. Nitorina ni nwọn ṣe wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa, nitoripe awa kò fẹ ìmọ ipa ọ̀na rẹ! Kini Olodumare ti awa o fi ma sin i? ere kili a o si jẹ bi awa ba gbadura si i! Kiyesi i, alafia wọn kò si nipa ọwọ wọn, ìmọ enia buburu jina si mi rére.
Job 21:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Jobu dáhùn pé, “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára, kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ́ ìtùnú fun yín. Ẹ farabalẹ̀, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, lẹ́yìn náà, ẹ lè máa fi mí ṣẹ̀sín ǹṣó. Ṣé eniyan ni mò ń bá rojọ́ ni? Kí ló dé tí n óo fi mú sùúrù? Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu. Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi, ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè, tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára? Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọn di eniyan pataki pataki lójú ayé wọn. Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà. Àwọn mààlúù wọn ń gùn, wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè. Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá. Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin, wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù. Wọn a máa gbé inú ọlá, wọn a sì máa kú ikú alaafia. Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀! A kò fẹ́ mọ òfin rẹ. Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín? Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’ Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà, nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
Job 21:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé: “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi. Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo. “Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí? Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀? Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín. Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí, ìwárìrì sì mú mi lára. Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa? Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn. Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn. Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun; Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri. Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè. Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà. Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i? Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.