Job 14:7-22

Job 14:7-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá. Bi gbongbo rẹ̀ tilẹ di ogbó ninu ilẹ, ti kukute rẹ̀ si kú ni ilẹ. Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko. Ṣugbọn enia kú, a si ṣàn danu; ani enia jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, on ha da? Bi omi ti itán ninu ipa odò, ti odò si ifà ti si igbẹ. Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn. A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ìkọkọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi. Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de. Iwọ iba pè, emi iba si da ọ lohùn, iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ. Ṣugbọn nisisiyi iwọ nkaye iṣisẹ mi, iwọ kò fà ọwọ rẹ kuro nitori ẹ̀ṣẹ mi. A fi edidi di irekọja mi sinu àpo, iwọ si rán aiṣedede mi pọ̀. Ati nitotọ oke nla ti o ṣubu, o dasan, a si ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀. Omi a ma yinrin okuta, iwọ a si mu omi ṣàn bo ohun ti o hù jade lori ilẹ, iwọ si sọ ireti enia di ofo. Iwọ si ṣẹgun rẹ̀ lailai, on si kọja lọ iwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o si ran a lọ kuro. Awọn ọmọ rẹ̀ bọ́ si ipo ọlá, on kò si mọ̀, nwọn si rẹ̀ silẹ, on kò si kiyesi i lara wọn. Ṣugbọn ẹran-ara rẹ̀ ni yio ri irora, ọkàn rẹ̀ ni yio si ma ni ibinujẹ ninu rẹ̀.

Job 14:7-22 Yoruba Bible (YCE)

“Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú, bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ, yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn. Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì, bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí. Bí adágún omi tíí gbẹ, ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn, tí kì í sìí jí mọ́, títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí, tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun. Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì, kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀, ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi. Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́? N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi, n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé. O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn, o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi, o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi. O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò, o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀. “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú, a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀. Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta, tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo. O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ, o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ. Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i. Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”

Job 14:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀; Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn. Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù; Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́. “Bí omi ti í tán nínú ipa odò, àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn. “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi! Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé. Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn; ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi; ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi? A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀. “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀. Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo. Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ! Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò. Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn. Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”