JOBU 14:7-22

JOBU 14:7-22 YCE

“Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú, bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ, yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn. Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì, bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí. Bí adágún omi tíí gbẹ, ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn, tí kì í sìí jí mọ́, títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí, tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun. Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì, kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀, ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi. Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́? N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi, n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé. O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn, o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi, o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi. O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò, o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀. “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú, a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀. Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta, tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo. O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ, o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ. Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i. Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”