Job 12:1-12
Job 12:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOBU si dahùn o si wipe, Kò si ani-ani nibẹ̀, ṣugbọn ẹnyin li awọn enia na, ọgbọ́n yio si kú pẹlu nyin. Ṣugbọn emi ni iyè ninu gẹgẹ bi ẹnyin: emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani kò mọ̀ nkan bi iru wọnyi? Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà. Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀. Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn. Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ. Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ. Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi? Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye. Eti ki idán ọ̀rọ wò bi? tabi adùn ẹnu ki isi tọ onjẹ rẹ̀ wò? Awọn arugbo li ọgbọ́n wà fun, ati ninu gigùn ọjọ li oye.
Job 12:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Jobu dáhùn pé: “Láìsí àní àní, ẹ̀yin ni agbẹnusọ gbogbo eniyan, bí ẹ bá jáde láyé, ọgbọ́n kan kò tún ní sí láyé mọ́. Bí ẹ ti ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ní, ẹ kò sàn jù mí lọ. Ta ni kò mọ irú nǹkan, tí ẹ̀ ń sọ yìí? Mo wá di ẹlẹ́yà lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi, èmi tí mò ń ké pe Ọlọrun, tí ó sì ń dá mi lóhùn; èmi tí mo jẹ́ olódodo ati aláìlẹ́bi, mo wá di ẹlẹ́yà. Lójú ẹni tí ara tù, ìṣòro kì í báni láìnídìí. Lójú rẹ̀, ẹni tí ó bá ṣìṣe ni ìṣòro wà fún. Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia, àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu, àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn. “Ṣugbọn, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹranko, wọn óo sì kọ́ ọ, bi àwọn ẹyẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ; tabi kí o bi àwọn koríko, wọn yóo sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóo sì ṣe àlàyé fún ọ. Ta ni kò mọ̀ ninu gbogbo wọn pé OLUWA ló ṣe èyí? Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà, ati ẹ̀mí gbogbo eniyan. Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò? “Àgbà ló ni ọgbọ́n, àwọn ogbó tí wọ́n ti pẹ́ láyé ni wọ́n ni òye.
Job 12:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé: “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín! Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: èmi kò kéré sí i yín: àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí? “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn: à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà. Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà, gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀. Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ. Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú Òkun yóò sì sọ fún ọ. Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ OLúWA ni ó ṣe nǹkan yìí? Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé. Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí? Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún, àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.