Job 10:8-22

Job 10:8-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọwọ rẹ li o ti dá mi, ti o si mọ mi pọ̀ yikakiri; sibẹ iwọ si mbà mi jẹ́. Emi bẹ̀ ọ ranti pe iwọ ti mọ mi bi amọ̀; iwọ o ha si tun mu mi pada lọ sinu erupẹ? Iwọ kò ha ti tu mi dà jade bi wàra, iwọ kò si mu mi dipọ̀ bi wàrakasi? Iwọ sa ti fi awọ ati ẹran-ara wọ̀ mi, iwọ si fi egungun ati iṣan ṣọgbà yi mi ká. Iwọ ti fun mi li ẹmi ati oju rere, ibẹ̀wo rẹ si pa ọkàn mi mọ́. Nkan wọnyi ni iwọ si ti fi pamọ ninu rẹ; emi mọ̀ pe, eyi mbẹ lọdọ rẹ. Bi mo ba ṣẹ̀, nigbana ni iwọ sàmi si mi, iwọ kì yio si dari aiṣedede mi ji. Bi mo ba ṣe ẹni-buburu, egbé ni fun mi! bi mo ba si ṣe ẹni-rere, bẹ̃li emi kò si le igbe ori mi soke. Emi damu, mo si wo ipọnju mi. Nitoriti npọ̀ si i: iwọ ndẹ mi kiri bi kiniun; ati pẹlu, iwọ a si fi ara rẹ hàn fun mi ni iyanju. Iwọ si tun sọ awọn ẹlẹri rẹ si mi di ọtun, iwọ si sọ irunu rẹ di pipọ si mi, ayipada ati ogun dó tì mi. Njẹ nitorina iwọ ha ṣe bí mi jade lati inu wá? A! emi iba kúku ti kú, ojukoju kì ba ti ri mi! Emi iba dabi ẹniti kò si ri, a ba ti gbe mi lati inu lọ si isà-okú. Ọjọ mi kò ha kuru bi? dawọ duro, ki o si jọwọ mi jẹ ki emi fi aiya balẹ diẹ. Ki emi ki o to lọ sibi ti emi kì yio pada sẹhin mọ́, ani si ilẹ òkunkun ati ojiji ikú. Ilẹ òkunkun bi òkunkun tikararẹ̀, ati ti ojiji ikú, laini èto, nibiti imọlẹ dabi òkunkun.

Job 10:8-22 Yoruba Bible (YCE)

Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi, ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run. Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí, ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni? Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà, tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè? Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí, tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀. O fún mi ní ìyè, o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró. Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ, mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé, bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi, o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà. Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé, ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn, nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀. Bí mo bá ṣe àṣeyọrí, o óo máa lépa mi bíi kinniun; ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára. O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí, O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ, O mú kí ogun mìíràn dó tì mí. “Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi? Ìbá sàn kí n ti kú, kí ẹnikẹ́ni tó rí mi. Wọn ìbá má bí mi rárá, kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì. Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé? Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀, kí n tó pada síbi tí mo ti wá, sí ibi òkùnkùn biribiri, ibi òkùnkùn ati ìdàrúdàpọ̀, níbi tí ìmọ́lẹ̀ ti dàbí òkùnkùn.”

Job 10:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi. Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run. Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀; ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀? Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà, ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì? Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí, ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká. Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere, ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́. “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ; èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ. Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì. Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi! Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè. Èmi dààmú, mo si wo ìpọ́njú mi. Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún; àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú. Ìwọ sì tún mun àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi; Àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun. “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá? Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi. Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè, À bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú. Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá! Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi. Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan. Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́, Àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú. Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀, Àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu, Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”