Job 10:1-7
Job 10:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
AGARA ìwa aiye mi da mi tan, emi o tú aroye mi sode lọdọ mi, emi o ma sọ ninu kikorò ibinujẹ ọkàn mi. Emi o wi fun Ọlọrun pe, o jare! máṣe dá mi lẹbi; fi hàn mi nitori idi ohun ti iwọ fi mba mi jà. O ha tọ́ si ọ ti iwọ iba ma tẹ̀mọlẹ̀, ti iwọ iba fi ma gan iṣẹ ọwọ rẹ, ti iwọ o fi ma tan imọlẹ si ìmọ enia buburu? Oju rẹ iha ṣe oju enia bi? tabi iwọ a ma riran bi enia ti iriran? Ọjọ rẹ ha dabi ọjọ enia, ọdun rẹ ha dabi ọdun enia? Ti iwọ fi mbere aiṣedẽde mi, ti iwọ si fi wa ẹ̀ṣẹ mi ri? Iwọ mọ̀ pe emi kì iṣe oniwa-buburu, kò si sí ẹniti igbà kuro li ọwọ rẹ.
Job 10:1-7 Yoruba Bible (YCE)
“Ayé sú mi, nítorí náà n kò ní dákẹ́ ìráhùn; n óo sọ̀rọ̀ pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn. N óo sọ fún Ọlọrun pé kí ó má dá mi lẹ́bi; kí ó sì jẹ́ kí n mọ ìdí tí ó fi ń bá mi jà. Ṣé ohun tí ó dára ni, Ọlọrun pé kí o máa ni eniyan lára, kí o kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, kí o sì fẹ́ràn ète ẹni ibi? Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan? Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i? Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí? Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan? Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi, tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.
Job 10:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Agara ìwà ayé mi dá mi tán, èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi. Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dá mi lẹ́bi; fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà. Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú. Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí? Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran? Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn, ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn? Tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi, tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí? Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú, kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?