Jer 21:8-9
Jer 21:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati fun enia yi ni ki iwọ ki o wipe, Bayi li Oluwa wi; Sa wò o, emi fi ọ̀na ìye ati ọ̀na ikú lelẹ niwaju nyin. Ẹniti o ba joko ninu ilu yi, yio ti ipa idà kú, ati nipa ìyan ati nipa àjakalẹ-àrun: ṣugbọn ẹniti o ba jade ti o si ṣubu si ọwọ awọn ara Kaldea ti o dó tì nyin, yio yè, ẹmi rẹ̀ yio si dabi ijẹ fun u.
Jer 21:8-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Sọ fún àwọn eniyan yìí pé èmi OLUWA ni mo la ọ̀nà meji níwájú wọn: ọ̀nà ìyè ati ọ̀nà ikú. Ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo pa ẹni tí ó bá dúró sinu ìlú yìí; ṣugbọn ẹni tí ó bá jáde tí ó sì fa ara rẹ̀ fún àwọn ará Kalidea, tí ó gbé ogun tì yín, yóo yè, yóo dàbí ẹni tó ja àjàbọ́.
Jer 21:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Síwájú sí i, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Babeli tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.