Jer 21:8-9

Jer 21:8-9 YBCV

Ati fun enia yi ni ki iwọ ki o wipe, Bayi li Oluwa wi; Sa wò o, emi fi ọ̀na ìye ati ọ̀na ikú lelẹ niwaju nyin. Ẹniti o ba joko ninu ilu yi, yio ti ipa idà kú, ati nipa ìyan ati nipa àjakalẹ-àrun: ṣugbọn ẹniti o ba jade ti o si ṣubu si ọwọ awọn ara Kaldea ti o dó tì nyin, yio yè, ẹmi rẹ̀ yio si dabi ijẹ fun u.