Jer 2:20-30

Jer 2:20-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitori ni igba atijọ iwọ ti ṣẹ́ ajaga ọrun rẹ, iwọ si já idè rẹ; iwọ si wipe, Emi kì o sìn, nitori lori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo ni iwọ nṣe panṣaga. Ṣugbọn emi ti gbin ọ ni ajara ọlọla, irugbin rere patapata: ẽṣe ti iwọ fi yipada di ẹka ajara ajeji si mi? Nitori iwọ iba wẹ ara rẹ ni ẽru, ki o si mu ọṣẹ pupọ, ẽri ni ẹ̀ṣẹ rẹ niwaju mi sibẹsibẹ, li Oluwa Ọlọrun wi. Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka. Kẹtẹkẹtẹ igbẹ ti ima gbe aginju, ninu ifẹ ọkàn rẹ̀ ti nfa ẹfufu, li akoko rẹ̀, tani le yi i pada? gbogbo awọn ti nwá a kiri kì yio da ara wọn li agara, nwọn o ri i li oṣu rẹ̀. Da ẹsẹ̀ rẹ duro ni aiwọ bàta, ati ọfun rẹ ninu ongbẹ: ṣugbọn iwọ wipe, lasan ni! bẹ̃kọ, nitoriti emi ti fẹ awọn alejo, awọn li emi o tọ̀ lẹhin. Gẹgẹ bi oju ti itì ole nigbati a ba mu u, bẹ̃li oju tì ile Israeli; awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn pẹlu. Ti nwọn wi fun igi pe, Iwọ ni baba mi; ati fun okuta pe, iwọ li o bi mi. Nitori nwọn ti yi ẹ̀hìn wọn pada si mi kì iṣe iwaju wọn: ṣugbọn ni igba ipọnju wọn, nwọn o wipe, Dide, ki o gbani. Njẹ nibo li awọn ọlọrun rẹ wà, ti iwọ ti da fun ara rẹ? jẹ ki nwọn ki o dide, bi nwọn ba le gba ọ nigba ipọnju rẹ, nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃li ọlọrun rẹ, iwọ Juda. Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi. Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun.

Jer 2:20-30 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA wí pé, “Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín, tí ẹ sì ti tú ìdè yín; tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí. Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè, ati lábẹ́ gbogbo igi tútù; ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga. Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́, tí èso rẹ̀ dára. Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata, tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò? Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín, tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀, sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi. Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́; ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali? Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì, kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣe bí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀; tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀. Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára, tí ń ṣí imú kiri, nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún. Ta ló lè dá a dúró? Kí akọ tí ó bá ń wá a má wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala, nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó. Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli, má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́. Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí, nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́, n óo sì wá wọn kiri.’ ” OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín, tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín; nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi. Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là. “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà? Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín! Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda. Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò? Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni, wọn kò gba ẹ̀kọ́. Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun, bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.

Jer 2:20-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà. Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá, Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,” ni OLúWA Olódùmarè wí. “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́; Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ tí ń sá síhìn-ín sọ́hùn-ún. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ, ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara, nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀. Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’ “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli— àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú. Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’ àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’ wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọ ojú sí mi síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’ Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnrayín ha a wà? Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda. “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí? Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,” ni OLúWA wí. “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí. Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.