Jeremiah 2:20-30

Jeremiah 2:20-30 YCB

“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà. Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá, Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,” ni OLúWA Olódùmarè wí. “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́; Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ tí ń sá síhìn-ín sọ́hùn-ún. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ, ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara, nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀. Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’ “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli— àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú. Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’ àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’ wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọ ojú sí mi síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’ Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnrayín ha a wà? Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda. “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí? Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,” ni OLúWA wí. “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí. Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.