JEREMAYA 17:5-6

JEREMAYA 17:5-6 YCE

OLUWA ní, “Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan, tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀; tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀, nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i. Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà, ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.