Isa 14:1-4
Isa 14:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI Oluwa yio ṣãnu fun Jakobu, yio si tun yan Israeli, yio si mu wọn gbe ilẹ wọn; alejò yio si dapọ̀ mọ wọn, nwọn o si faramọ ile Jakobu. Awọn enia yio si mu wọn, nwọn o si mu wọn wá si ipò wọn: ile Israeli yio si ni wọn ni ilẹ Oluwa, fun iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin: awọn ti o ti kó wọn ni igbekun ni nwọn o kó ni igbekun; nwọn o si ṣe akoso aninilara wọn. Yio si ṣe li ọjọ ti Oluwa yio fun ọ ni isimi kuro ninu ibanujẹ rẹ, ati kuro ninu ijaiya rẹ, ati kuro ninu oko-ẹru lile nibiti a ti mu ọ sìn, Ni iwọ o si fi ọba Babiloni ṣẹ̀fẹ yi, ti iwọ o si wipe, Aninilara nì ha ti ṣe dakẹ! alọnilọwọgbà wura dakẹ!
Isa 14:1-4 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára. Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe, ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé
Isa 14:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA yóò fi àánú hàn fún Jakọbu, yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn. Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ OLúWA. Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn. Ní ọjọ́ tí OLúWA yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!