Isaiah 14:1-4

Isaiah 14:1-4 YCB

OLúWA yóò fi àánú hàn fún Jakọbu, yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn. Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ OLúWA. Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn. Ní ọjọ́ tí OLúWA yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!