Isa 13:6-9
Isa 13:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá. Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́. Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná. Kiyesi i, ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, o ni ibi ti on ti ikannú ati ibinu gbigboná, lati sọ ilẹ na di ahoro: yio si pa awọn ẹlẹṣẹ run kuro ninu rẹ̀.
Isa 13:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ pohùnréré ẹkún, nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé, yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare. Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ, ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì; ẹnu yóo sì yà wọ́n. Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn, wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí; wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu, ojú yóo sì tì wọ́n. Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán, tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro, ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
Isa 13:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ hu, nítorí ọjọ́ OLúWA súnmọ́ tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ. Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ, ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sì gbinájẹ. Kíyèsi i, ọjọ́ OLúWA ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro, àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.