AISAYA 13:6-9

AISAYA 13:6-9 YCE

Ẹ pohùnréré ẹkún, nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé, yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare. Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ, ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì; ẹnu yóo sì yà wọ́n. Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn, wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí; wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu, ojú yóo sì tì wọ́n. Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán, tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro, ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.