Hos 12:3-5
Hos 12:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun. Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ; Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀.
Hos 12:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì. Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀
Hos 12:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀ o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀ Ó bá OLúWA ní Beteli Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, àní OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLúWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀