Hosea 12:3-5

Hosea 12:3-5 YCB

Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀ o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀ Ó bá OLúWA ní Beteli Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀, àní OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLúWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀