Heb 3:1-11

Heb 3:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa. Ẹ rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí Ọlọrun tí ó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣe oloòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun. Nítorí bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti ní ọlá ju ilé tí ó kọ́ lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jesu yìí ní ọlá ju Mose lọ. Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo. Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni. Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀, ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀, nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò, tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún. Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn. Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn. Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’ Ni mo bá búra pẹlu ibinu, pé wọn kò ní dé ibi ìsinmi mi.”

Heb 3:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; Ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí: “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀, bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù: Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún. Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn; wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’ Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”