NITORINA ẹnyin ará mimọ́, alabapín ìpe ọ̀run, ẹ gbà ti Aposteli ati Olori Alufa ijẹwọ wa ro, ani Jesu; Ẹniti o ṣe olõtọ si ẹniti o yàn a, bi Mose pẹlu ti ṣe ninu gbogbo ile rẹ̀. Nitori a kà ọkunrin yi ni yiyẹ si ogo jù Mose lọ niwọn bi ẹniti o kọ́ ile ti li ọla jù ile lọ. Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun. Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin; Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin. Nitorina gẹgẹbi Ẹmí Mimọ́ ti wi, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu, bi li ọjọ idanwò li aginjù: Nibiti awọn baba nyin dán mi wò, nipa wiwadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi li ogoji ọdún. Nitorina inu mi bajẹ si iran na, mo si wipe, Nigbagbogbo ni nwọn nṣìna li ọkàn wọn; nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi. Bi mo ti bura ni ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi.
Kà Heb 3
Feti si Heb 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 3:1-11
8 Days
What is rest? What does it mean to enter into God’s rest? What exactly are we resting from? As we journey through Part Two of Nine devotional plans walking us through the book of Hebrews, we discover how God defines rest, how we enter this rest and how we grow from this position of rest.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò