Heb 1:1-7
Heb 1:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni. Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu; Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke; O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ. Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi? Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u. Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná.
Heb 1:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀. Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé. Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ. Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ. Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ?” Tabi tí ó sọ fún pé, “Èmi yóo jẹ́ baba fún un, òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?” Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé, “Kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọrun foríbalẹ̀ fún un.” Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé, “Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù, tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”
Heb 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè. Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn. Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ”? Àti pẹ̀lú pé; “Èmi yóò jẹ́ baba fún un, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”? Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.” Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé; “Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”