HEBERU 1:1-7

HEBERU 1:1-7 YCE

Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀. Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé. Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ. Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ. Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ?” Tabi tí ó sọ fún pé, “Èmi yóo jẹ́ baba fún un, òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?” Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé, “Kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọrun foríbalẹ̀ fún un.” Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé, “Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù, tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”