Gẹn 4:8-9
Gẹn 4:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa. OLUWA si wi fun Kaini pe, Nibo ni Abeli arakunrin rẹ wà? O si wipe, Emi kò mọ̀; emi iṣe olutọju arakunrin mi bi?
Gẹn 4:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa. OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”
Gẹn 4:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á. Nígbà náà ni OLúWA béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?”