JẸNẸSISI 4:8-9

JẸNẸSISI 4:8-9 YCE

Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa. OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”