Gal 5:5-7 - Compare All Versions
Gal 5:5-7 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ. Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ?
Pín
Gal 5 YBCVGal 5:5-7 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́?
Pín
Gal 5 BMYOGal 5:5-7 YCE (Yoruba Bible)
Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́?
Pín
Gal 5 YCE