GALATIA 5:5-7

GALATIA 5:5-7 YCE

Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́?