Esr 10:5-6
Esr 10:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Esra si dide, o si mu awọn olori ninu awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Israeli bura pe, awọn o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Nwọn si bura. Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ.
Esr 10:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹsira bá dìde nílẹ̀, ó wí fún gbogbo àwọn olórí alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n búra pé wọn yóo ṣe gẹ́gẹ́ bí Ṣekanaya ti sọ, wọ́n sì búra. Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé.
Esr 10:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Esra dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo Israẹli sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra. Nígbà náà ni Esra padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jehohanani ọmọ Eliaṣibu. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn.