Esr 10:5-6

Esr 10:5-6 YBCV

Esra si dide, o si mu awọn olori ninu awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Israeli bura pe, awọn o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Nwọn si bura. Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ.