Eks 4:1-9

Eks 4:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Mose dáhùn pé, “Wọn kò ní gbà mí gbọ́, wọn kò tilẹ̀ ní fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọn yóo wí pé, OLUWA kò farahàn mí.” OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.” OLUWA ní, “Sọ ọ́ sílẹ̀.” Mose bá sọ ọ́ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò, Mose bá sá sẹ́yìn. Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o mú un ní ìrù.” Mose nawọ́ mú un, ejò náà sì pada di ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀. OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.” OLUWA tún wí fún un pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá. Nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́. Bí wọn kò bá gba àwọn àmì mejeeji wọnyi gbọ́, tí wọ́n sì kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, lọ bu omi díẹ̀ ninu odò Naili kí o sì dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀; omi náà yóo di ẹ̀jẹ̀ bí o bá ti dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀.”

Eks 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mose dáhùn ó sì wí pé; “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘OLúWA kò farahàn ọ́’?” Ní ìgbà náà ni OLúWA sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?” Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni.” OLúWA sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.” Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un. Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, “na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀. OLúWA sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn: Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.” Ní ìgbà náà ni OLúWA wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ó sì wí pé, “Nísinsin yìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tókù. Ní ìgbà náà ni OLúWA wí pé; “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba ààmì méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Naili kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”