Oni 3:19-20
Oni 3:19-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀. Nibikanna ni gbogbo wọn nlọ; lati inu erupẹ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn si tun pada di erupẹ.
Oni 3:19-20 Yoruba Bible (YCE)
nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí.
Oni 3:19-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí.