ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:19-20

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:19-20 YCE

nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí.