Amo 9:13-14
Amo 9:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́. Emi o si tun mu igbèkun Israeli enia mi padà bọ̀, nwọn o si kọ́ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn.
Amo 9:13-14 Yoruba Bible (YCE)
“Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tán kí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé. Ọgbà àjàrà yóo so, tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tán kí àkókò ati gbin òmíràn tó dé. Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké. N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada, wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́, wọn yóo sì máa gbé inú wọn. Wọn yóo gbin àjàrà, wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀. Wọn yóo ṣe ọgbà, wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀.
Amo 9:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLúWA wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀ Tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèkéé. Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.