Iṣe Apo 9:23-29
Iṣe Apo 9:23-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a: Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n. Nigbati Saulu si de Jerusalemu, o pete ati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ-ẹhin: gbogbo nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, nitori nwọn kò gbagbọ́ pe ọmọ-ẹhin kan ni. Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu. O si wà pẹlu wọn, o nwọle o si njade ni Jerusalemu. O si nfi igboiya sọ̀rọ li orukọ Jesu Oluwa, o nsọrọ lòdi si awọn ara Hellene, o si njà wọn niyàn: ṣugbọn nwọn npete ati pa a.
Iṣe Apo 9:23-29 Yoruba Bible (YCE)
Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á. Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á. Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú. Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku. Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa, ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á.
Iṣe Apo 9:23-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n. Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni. Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.